Kristiẹniti
pada

Galatians 6

itumọ ẹrọ: ko si itumọ ti a tẹjade ti iwe yii si ede rẹ sibẹsibẹ

1Ẹ̀yin ará, bí a tilẹ̀ bá ẹnìkan nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan, ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ẹ tún irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe nínú ẹ̀mí ìwà tútù; kí ìwọ tìkára rẹ kíyèsára, kí a má baà dán ìwọ náà wò.

2Ẹ máa ru ẹrù ara yín lẹ́nìkínní kejì, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin yóò sì mú òfin Kristi ṣẹ.

3Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé nǹkan ni òun jẹ́, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ.

4Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù dán iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà ni yóò ní ìṣògo nínú ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe nínú ẹlòmíràn.

5Nítorí olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀.

6Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà pín ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni.

7Ẹ má ṣe tàn ara yín jẹ: a kì í fi Ọlọ́run ṣẹ̀sín: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá gbìn, èyí náà ni yóò kórè rẹ̀ pẹ̀lú.

8Nítorí ẹni tí ó bá gbìn sípa ti ara rẹ̀, láti ara wá ni yóò ti kórè ìbàjẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbìn sípa ti Ẹ̀mí, láti inú Ẹ̀mí wá ni yóò ti kórè ìyè àìnípẹ̀kun.

9Kí ó má sì ṣe rẹ̀ wá nínú rere ṣíṣe: nítorí ní àkókò tí ó wọ̀ a ó kórè, bí àárẹ̀ kò bá mú wa.

10Nítorí náà, bí a ti rí ààyè, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe rere sí gbogbo ènìyàn, pàápàá sí àwọn ti agbo ilé ìgbàgbọ́.

11Ẹ wò bí àwọn lẹ́tà tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ sí yín ti tóbi tó!

12Iye àwọn tí ń fẹ́ fi àwọ̀ rere hàn nípa ti ara, àwọn wọ̀nyí ni ń fi agbára mú yín láti kọlà; kìkì nítorí kí a má baà ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi.

13Nítorí àwọn tí a kọlà náà pàápàá kò pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ kí ẹ kọlà, kí wọn lè ṣògo nínú ara yín.

14Ṣùgbọ́n kí a má rí i pé èmi ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Olúwa wa Jesu Kristi, nípa èyí tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé.

15Nítorí kì í ṣe ikọlà tàbí àìkọlà ló jẹ́ nǹkan kan. Ohun tí ó kà ni ẹ̀dá tuntun.

16Àlàáfíà àti àánú fún gbogbo àwọn tí ń rìn nípa ìlànà yìí, àní fún Israẹli ti Ọlọ́run.

17Láti ìsinsìnyí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu, nítorí mo ru àwọn ààmì Jesu lára mi.

18Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín, ẹ̀yin ará. Àmín.

orisun: Berean Standard Bible

WEBREATH · 11:11

«He himself gives everyone life and breath and everything else» — Acts 17:25

Breath is one for all: everyone lives by it, whoever they are and whatever they believe. Every day at 11:11 local time people stop for sixty seconds, breathe, and thank GOD for the breath — each in their own words, each within themselves. In that minute we are One Breath.

WEBREATH — the Minute at 11:11, your own local time — we are One Breath